Songtexte.com Drucklogo

Jagun Jagun Songtext
von BANTU

Jagun Jagun Songtext

Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀


Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d′abú-omi rú
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d'ọ̀dàn rú
Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m′igbó kìji-kìji
Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú
Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo
Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà
Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́
Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín
Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe
Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú
Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!
Arọnimaja ṣáagun!
Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí
Ohun l'awo Alágbàá'a, èyí tí ó fi ta b′aṣeégún lójú

Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

Songtext kommentieren

Log dich ein um einen Eintrag zu schreiben.
Schreibe den ersten Kommentar!

Quiz
Welcher Song ist nicht von Robbie Williams?

Fans

»Jagun Jagun« gefällt bisher niemandem.